-
Ẹ́kísódù 23:29Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Mi ò ní lé wọn kúrò níwájú yín láàárín ọdún kan, kí ilẹ̀ náà má bàa di ahoro, kí àwọn ẹranko búburú má bàa pọ̀ níbẹ̀ kí wọ́n sì ṣe yín lọ́ṣẹ́.+
-
-
Jóṣúà 13:2-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Àwọn ilẹ̀ tó ṣẹ́ kù nìyí:+ gbogbo ilẹ̀ àwọn Filísínì àti ti gbogbo àwọn ará Géṣúrì+ 3 (láti ẹ̀ka odò Náílì* tó wà ní ìlà oòrùn* Íjíbítì títí dé ààlà Ẹ́kírónì lọ sí àríwá, tí wọ́n máa ń pè ní ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì)+ pẹ̀lú ilẹ̀ àwọn alákòóso Filísínì márààrún,+ ìyẹn àwọn ará Gásà, àwọn ará Áṣídódì,+ àwọn ará Áṣíkẹ́lónì,+ àwọn ará Gátì+ àti àwọn ará Ẹ́kírónì;+ ilẹ̀ àwọn Áfímù+ 4 lọ sí apá gúúsù; gbogbo ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì; Méárà, tó jẹ́ ti àwọn ọmọ Sídónì,+ títí lọ dé Áfékì, dé ààlà àwọn Ámórì; 5 ilẹ̀ àwọn ará Gébálì+ àti gbogbo Lẹ́bánónì lápá ìlà oòrùn, láti Baali-gádì ní ìsàlẹ̀ Òkè Hámónì títí dé Lebo-hámátì;*+ 6 gbogbo àwọn tó ń gbé agbègbè olókè láti Lẹ́bánónì+ lọ dé Misirefoti-máímù;+ àti gbogbo àwọn ọmọ Sídónì.+ Mo máa lé wọn kúrò* níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ Kí o ṣáà rí i pé o pín in fún Ísírẹ́lì pé kó jẹ́ ogún wọn, bí mo ṣe pa á láṣẹ fún ọ.+
-