-
Diutarónómì 12:31Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
31 O ò gbọ́dọ̀ ṣe báyìí sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ, torí gbogbo ohun tí Jèhófà kórìíra ni wọ́n máa ń ṣe sí àwọn ọlọ́run wọn, kódà wọ́n máa ń sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná sí àwọn ọlọ́run wọn.+
-
-
Diutarónómì 18:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 “Tí ẹ bá ti dé ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín, ẹ ò gbọ́dọ̀ bá àwọn orílẹ̀-èdè yẹn ṣe àwọn ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe.+
-
-
Diutarónómì 18:12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Torí Jèhófà kórìíra ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, torí àwọn ohun ìríra yìí sì ni Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe máa lé wọn kúrò níwájú yín.
-