ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 23:40
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 40 Ní ọjọ́ kìíní, kí ẹ mú èso àwọn igi ńláńlá, àwọn imọ̀ ọ̀pẹ,+ àwọn ẹ̀ka igi eléwé púpọ̀ àti àwọn igi pọ́pílà tó wà ní àfonífojì, kí ẹ sì yọ̀+ níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín fún ọjọ́ méje.+

  • Diutarónómì 12:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Kí ẹ máa yọ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín,+ ẹ̀yin àti àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn ọmọbìnrin yín, àwọn ẹrúkùnrin yín, àwọn ẹrúbìnrin yín àti ọmọ Léfì tó wà nínú àwọn ìlú* yín, torí wọn ò fún un ní ìpín tàbí ogún kankan pẹ̀lú yín.+

  • Diutarónómì 12:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Iwájú Jèhófà Ọlọ́run yín ni kí ẹ ti jẹ ẹ́, níbi tí Jèhófà Ọlọ́run yín bá yàn,+ ẹ̀yin àti ọmọkùnrin yín, ọmọbìnrin yín, ẹrúkùnrin yín àti ẹrúbìnrin yín àti ọmọ Léfì tó wà nínú àwọn ìlú* yín; kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín nínú gbogbo ohun tí ẹ bá dáwọ́ lé.

  • Diutarónómì 14:23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 23 Iwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni kí o ti máa jẹ ìdá mẹ́wàá ọkà rẹ, wáìnì tuntun rẹ, òróró rẹ àti àwọn àkọ́bí nínú ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran rẹ, ní ibi tó yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà,+ kí o lè kọ́ láti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ nígbà gbogbo.+

  • Diutarónómì 14:26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 O lè wá fi owó náà ra ohunkóhun tó bá wù ọ́,* bíi màlúù, àgùntàn, ewúrẹ́, wáìnì àtàwọn ohun mímu míì tó ní ọtí àti ohunkóhun tí o bá fẹ́;* kí o jẹ ẹ́ níbẹ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o sì máa yọ̀, ìwọ àti agbo ilé rẹ.+

  • Sáàmù 32:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Ẹ máa yọ̀ nínú Jèhófà, kí inú yín sì máa dùn, ẹ̀yin olódodo;

      Ẹ kígbe ayọ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ọkàn yín dúró ṣinṣin.

  • Sáàmù 100:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  2 Ẹ fi ayọ̀ sin Jèhófà.+

      Ẹ fi igbe ayọ̀ wá síwájú rẹ̀.

  • Fílípì 4:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo nínú Olúwa. Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo sọ pé, Ẹ máa yọ̀!+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́