-
Nọ́ńbà 18:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Torí mo ti fi ìdá mẹ́wàá tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa mú wá fún Jèhófà ṣe ogún fún àwọn ọmọ Léfì. Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ fún wọn pé, ‘Wọn ò gbọ́dọ̀ ní ogún+ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’”
-
-
Diutarónómì 10:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Ìdí nìyẹn tí wọn ò fi fún Léfì ní ìpín tàbí ogún kankan pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀. Jèhófà ni ogún rẹ̀, bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe sọ fún un.+
-
-
Diutarónómì 14:28, 29Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
28 “Ní òpin ọdún mẹ́ta-mẹ́ta, kí o kó gbogbo ìdá mẹ́wàá èso rẹ ní ọdún yẹn jáde, kí o sì kó o sínú àwọn ìlú rẹ.+ 29 Ọmọ Léfì tí wọn ò fún ní ìpín tàbí ogún kankan pẹ̀lú rẹ, àjèjì, ọmọ aláìníbaba* àti opó tí wọ́n wà nínú àwọn ìlú rẹ máa wá, wọ́n á sì jẹun yó,+ kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ lè máa bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí ò ń ṣe.+
-