24 Torí màá lé àwọn orílẹ̀-èdè kúrò níwájú yín,+ màá sì mú kí ilẹ̀ yín fẹ̀, ilẹ̀ yín ò sì ní wọ ẹnikẹ́ni lójú nígbà tí ẹ bá ń gòkè lọ rí ojú Jèhófà Ọlọ́run yín lẹ́ẹ̀mẹta lọ́dún.
24 Gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹsẹ̀ tẹ̀ ló máa di tiyín.+ Láti aginjù títí dé Lẹ́bánónì, láti Odò, ìyẹn odò Yúfírétì, dé òkun* tó wà ní ìwọ̀ oòrùn ló máa jẹ́ ààlà yín.+