-
Diutarónómì 13:12-15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 “Nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú rẹ, èyí tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kí o máa gbé, tí o bá gbọ́ tí wọ́n sọ pé, 13 ‘Àwọn èèyàn tí kò ní láárí ti jáde láti àárín rẹ, kí wọ́n lè yí àwọn tó ń gbé ìlú wọn pa dà, wọ́n ń sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká lọ sin àwọn ọlọ́run míì,” àwọn ọlọ́run tí ẹ kò mọ̀,’ 14 rí i pé o yẹ ọ̀rọ̀ náà wò, kí o ṣe ìwádìí fínnífínní, kí o sì béèrè nípa rẹ̀;+ tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni wọ́n ṣe ohun ìríra yìí láàárín rẹ, 15 kí o rí i pé o fi idà pa àwọn tó ń gbé ìlú yẹn.+ Kí o fi idà pa ìlú náà àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ run pátápátá, títí kan àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀.+
-