-
1 Sámúẹ́lì 28:7-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Níkẹyìn, Sọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ bá mi wá obìnrin kan tí ó jẹ́ abẹ́mìílò,+ màá lọ wádìí lọ́wọ́ rẹ̀.” Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé: “Wò ó! Obìnrin kan tí ó jẹ́ abẹ́mìílò wà ní Ẹ́ń-dórì.”+
8 Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù pa ara dà, ó wọ aṣọ míì, ó sì lọ sọ́dọ̀ obìnrin náà ní òru pẹ̀lú méjì lára àwọn ọkùnrin rẹ̀. Ó ní: “Jọ̀wọ́, bá mi fi agbára ìbẹ́mìílò+ rẹ pe ẹni tí mo bá dárúkọ rẹ̀ fún ọ jáde.” 9 Ṣùgbọ́n, obìnrin náà sọ fún un pé: “Ó yẹ kí o mọ ohun tí Sọ́ọ̀lù ṣe dáadáa, bí ó ṣe mú àwọn abẹ́mìílò àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́ kúrò ní ilẹ̀ yìí.+ Kí wá nìdí tí o fi fẹ́ dẹkùn mú mi* kí wọ́n lè pa mí?”+ 10 Sọ́ọ̀lù wá fi Jèhófà búra fún un pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, o ò ní jẹ̀bi kankan lórí ọ̀rọ̀ yìí!” 11 Ni obìnrin náà bá sọ pé: “Ta ni kí n bá ọ pè jáde?” Ó fèsì pé: “Bá mi pe Sámúẹ́lì jáde.”
-