-
Nọ́ńbà 21:13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n sì pàgọ́ sí agbègbè Áánónì,+ tó wà ní aginjù tó bẹ̀rẹ̀ láti ààlà àwọn Ámórì, torí Áánónì ni ààlà Móábù, láàárín Móábù àti àwọn Ámórì.
-
-
Àwọn Onídàájọ́ 11:17, 18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Ísírẹ́lì wá ránṣẹ́ sí ọba Édómù+ pé: “Jọ̀ọ́, jẹ́ ká gba ilẹ̀ rẹ kọjá,” àmọ́ ọba Édómù ò gbà. Wọ́n tún ránṣẹ́ sí ọba Móábù,+ àmọ́ kò gbà. Ísírẹ́lì ò wá kúrò ní Kádéṣì.+ 18 Nígbà tí wọ́n rin aginjù, wọn ò gba inú ilẹ̀ Édómù+ àti ilẹ̀ Móábù kọjá. Apá ìlà oòrùn ilẹ̀ Móábù+ ni wọ́n gbà, wọ́n sì pàgọ́ sí agbègbè Áánónì; wọn ò wọnú ààlà Móábù,+ torí Áánónì ni ààlà Móábù.
-