-
Nọ́ńbà 20:17, 18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Jọ̀ọ́, jẹ́ ká gba ilẹ̀ rẹ kọjá. A ò ní gba inú oko kankan tàbí ọgbà àjàrà, a ò sì ní mu omi kànga kankan. Ojú Ọ̀nà Ọba la máa gbà, a ò ní yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì títí a fi máa kọjá ní ilẹ̀+ rẹ.’”
18 Àmọ́ Édómù sọ fún un pé: “Má gba ilẹ̀ wa kọjá. Tí o bá gbabẹ̀, idà ni màá wá fi pàdé rẹ.”
-
-
Diutarónómì 2:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Jèhófà wá sọ fún mi pé, ‘Má ṣe bá Móábù fa wàhálà kankan, má sì bá wọn jagun, torí mi ò ní fún ọ ní ìkankan lára ilẹ̀ rẹ̀ pé kó di tìrẹ, torí mo ti fún àwọn àtọmọdọ́mọ Lọ́ọ̀tì ní Árì kó lè di tiwọn.+
-
-
Diutarónómì 2:19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Tí o bá ti sún mọ́ ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì, má yọ wọ́n lẹ́nu, má sì múnú bí wọn, torí mi ò ní fún ọ ní ìkankan lára ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì kó lè di tìrẹ, nítorí mo ti fún àwọn àtọmọdọ́mọ Lọ́ọ̀tì kó lè di tiwọn.+
-