-
Jẹ́nẹ́sísì 34:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Ṣékémù sọ fún bàbá ọmọbìnrin náà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí n rí ojúure yín, màá sì fún yín ní ohunkóhun tí ẹ bá bi mí. 12 Ẹ lè béèrè owó orí ìyàwó tó pọ̀ gan-an àti ẹ̀bùn+ lọ́wọ́ mi. Mo ṣe tán láti fún yín ní ohunkóhun tí ẹ bá bi mí. Ẹ ṣáà fún mi ní ọmọbìnrin náà kí n fi ṣe aya.”
-
-
Ẹ́kísódù 22:16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 “Tí ọkùnrin kan bá fa ojú wúńdíá kan tí kò ní àfẹ́sọ́nà mọ́ra, tó sì bá a sùn, ó gbọ́dọ̀ san owó orí rẹ̀ kó lè di ìyàwó rẹ̀.+
-