-
Mátíù 19:3-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Àwọn Farisí wá bá a, wọ́n fẹ́ dán an wò, wọ́n sì bi í pé: “Ṣé ó bófin mu fún ọkùnrin láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ lórí gbogbo ẹ̀sùn?”+ 4 Ó dá wọn lóhùn pé: “Ṣé ẹ ò kà á pé ẹni tó dá wọn ní ìbẹ̀rẹ̀ dá wọn ní akọ àti abo,+ 5 ó sì sọ pé, ‘Torí èyí, ọkùnrin á fi bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, á sì fà mọ́ ìyàwó rẹ̀, àwọn méjèèjì á sì di ara kan’?+ 6 Tó fi jẹ́ pé wọn kì í ṣe méjì mọ́, àmọ́ wọ́n jẹ́ ara kan. Torí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí èèyàn kankan má ṣe yà á.”+ 7 Wọ́n sọ fún un pé: “Kí ló wá dé tí Mósè fi sọ pé ká fún un ní ìwé ẹ̀rí láti lé e lọ, ká sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀?”+ 8 Ó sọ fún wọn pé: “Torí pé ọkàn yín le ni Mósè ṣe yọ̀ǹda fún yín láti kọ ìyàwó yín sílẹ̀,+ àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀.+
-