20 kí wọ́n sì sọ fún àwọn àgbààgbà ìlú rẹ̀ pé, ‘Alágídí àti ọlọ̀tẹ̀ ni ọmọ wa yìí, kì í gbọ́ tiwa. Alájẹkì+ àti ọ̀mùtípara+ sì ni.’ 21 Kí gbogbo ọkùnrin ìlú rẹ̀ sọ ọ́ ní òkúta pa. Kí o mú ohun tó burú kúrò láàárín rẹ, tí gbogbo Ísírẹ́lì bá sì gbọ́, ẹ̀rù á bà wọ́n.+