19 Sọ fún àwọn èèyàn ilẹ̀ náà pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì nìyí: “Ọkàn wọn ò ní balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń jẹ oúnjẹ wọn, ẹ̀rù á sì máa bà wọ́n bí wọ́n ṣe ń mu omi wọn, torí ilẹ̀ wọn á di ahoro pátápátá+ torí ìwà ipá gbogbo àwọn tó ń gbé ibẹ̀.+