16 ó sọ pé: “‘Mo fi ara mi búra pé torí ohun tí o ṣe yìí,’ ni Jèhófà+ wí, ‘tí o kò kọ̀ láti fún mi ní ọmọ rẹ, ọ̀kan ṣoṣo+ tí o ní, 17 ó dájú pé màá bù kún ọ, ó sì dájú pé màá mú kí ọmọ rẹ pọ̀ bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti iyanrìn etí òkun,+ ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnubodè àwọn ọ̀tá+ rẹ̀ lọ́wọ́ wọn.