-
Diutarónómì 31:7, 8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Mósè wá pe Jóṣúà, ó sì sọ fún un níṣojú gbogbo Ísírẹ́lì pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára,+ torí ìwọ lo máa mú àwọn èèyàn yìí wọ ilẹ̀ tí Jèhófà búra fún àwọn baba ńlá wọn pé òun máa fún wọn, wàá sì fún wọn kí wọ́n lè jogún rẹ̀.+ 8 Jèhófà ló ń lọ níwájú rẹ, ó sì máa wà pẹ̀lú rẹ.+ Kò ní pa ọ́ tì, kò sì ní fi ọ́ sílẹ̀. Má bẹ̀rù, má sì jáyà.”+
-