12 “Àwọn ẹ̀yà yìí ló máa dúró lórí Òkè Gérísímù+ láti súre fún àwọn èèyàn náà tí ẹ bá ti sọdá Jọ́dánì: Síméónì, Léfì, Júdà, Ísákà, Jósẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì. 13 Àwọn ẹ̀yà yìí ló sì máa dúró lórí Òkè Ébálì+ láti kéde ègún: Rúbẹ́nì, Gádì, Áṣérì, Sébúlúnì, Dánì àti Náfútálì.