5 Gbàrà tí gbogbo ọba àwọn Ámórì,+ tí wọ́n wà lápá ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì àti gbogbo ọba àwọn ọmọ Kénáánì,+ tí wọ́n wà létí òkun gbọ́ pé Jèhófà ti mú kí omi Jọ́dánì gbẹ níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí wọ́n fi sọdá, ọkàn wọn domi,+ kò sì sí ẹni tó ní ìgboyà mọ́ torí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+