-
Nọ́ńbà 21:33, 34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
33 Lẹ́yìn náà, wọ́n pa dà, wọ́n sì lọ gba Ọ̀nà Báṣánì. Ógù+ ọba Báṣánì àti gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ sì jáde wá gbéjà kò wọ́n ní Édíréì.+ 34 Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Má bẹ̀rù rẹ̀,+ torí màá fi òun àti gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ àti ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́,+ ohun tí o ṣe sí Síhónì, ọba àwọn Ámórì tó gbé ní Hẹ́ṣíbónì+ gẹ́lẹ́ ni wàá ṣe sí i.”
-
-
Diutarónómì 3:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Torí náà, Jèhófà Ọlọ́run wa tún fi Ógù ọba Báṣánì àti gbogbo èèyàn rẹ̀ lé wa lọ́wọ́, a sì bá a jà títí ìkankan nínú àwọn èèyàn rẹ̀ ò fi ṣẹ́ kù.
-
-
Jóṣúà 9:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Wọ́n fèsì pé: Ọ̀nà tó jìn gan-an ni àwa ìránṣẹ́ rẹ ti wá,+ torí a gbọ́ nípa orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, òkìkí rẹ̀ kàn dé ọ̀dọ̀ wa, a sì ti gbọ́ nípa gbogbo ohun tó ṣe ní Íjíbítì+ 10 àti gbogbo ohun tó ṣe sí àwọn ọba Ámórì méjèèjì tí wọ́n wà ní òdìkejì* Jọ́dánì, ìyẹn Síhónì+ ọba Hẹ́ṣíbónì àti Ógù+ ọba Báṣánì, tó wà ní Áṣítárótì.
-