-
Àwọn Onídàájọ́ 1:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Bákan náà, àwọn ọkùnrin Júdà bá Jerúsálẹ́mù+ jà, wọ́n sì gbà á; wọ́n fi idà pa á run, wọ́n sì dáná sun ìlú náà.
-
-
Àwọn Onídàájọ́ 1:21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Àmọ́ àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ò lé àwọn ará Jébúsì tó ń gbé Jerúsálẹ́mù kúrò, torí náà, àwọn ará Jébúsì ṣì ń bá àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì gbé ní Jerúsálẹ́mù títí dòní.+
-
-
Àwọn Onídàájọ́ 19:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Nígbà tí wọ́n dé tòsí Jébúsì, ilẹ̀ ti ń ṣú lọ. Ìránṣẹ́ náà wá bi ọ̀gá rẹ̀ pé: “Ṣé ká dúró ní ìlú àwọn ará Jébúsì yìí ká sì sun ibẹ̀ mọ́jú?”
-