-
Diutarónómì 33:13-15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Ó sọ nípa Jósẹ́fù pé:+
“Kí Jèhófà bù kún ilẹ̀ rẹ̀+
Pẹ̀lú àwọn ohun tó dáa láti ọ̀run,
Pẹ̀lú ìrì àti omi tó ń sun láti ilẹ̀,+
14 Pẹ̀lú àwọn ohun tó dáa tí oòrùn mú jáde,
Àti ohun tó dáa tó ń mú jáde lóṣooṣù,+
15 Pẹ̀lú àwọn ohun tó dáa jù láti àwọn òkè àtijọ́,*+
Àti àwọn ohun tó dáa láti àwọn òkè tó ti wà tipẹ́,
-
Jóṣúà 17:17, 18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Jóṣúà wá sọ fún ilé Jósẹ́fù, ó sọ fún Éfúrémù àti Mánásè pé: “Èèyàn púpọ̀ ni yín, ẹ sì lágbára gan-an. Kì í ṣe ilẹ̀ kan péré la máa fi kèké pín fún yín,+ 18 àmọ́ agbègbè olókè náà tún máa di tiyín.+ Bó tiẹ̀ jẹ́ pé igbó ni, ẹ máa ṣán an, ibẹ̀ ló sì máa jẹ́ ìkángun ilẹ̀ yín. Torí ẹ máa lé àwọn ọmọ Kénáánì kúrò níbẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lágbára, wọ́n sì ní àwọn kẹ̀kẹ́ ogun tó ní dòjé irin.”*+
-
-
-