5 Ààlà àwọn àtọmọdọ́mọ Éfúrémù ní ìdílé-ìdílé nìyí: Ààlà ogún wọn lápá ìlà oòrùn ni Ataroti-ádárì+ títí dé Bẹti-hórónì Òkè,+ 6 ó sì dé òkun. Míkímẹ́tátì+ wà ní àríwá, ààlà náà sì yí gba apá ìlà oòrùn lọ sí Taanati-ṣílò, ó sì gba ìlà oòrùn lọ sí Jánóà.