ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jóṣúà 15:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Ààlà náà dé Àfonífojì Ọmọ Hínómù,+ ó dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn ará Jébúsì+ ní gúúsù, ìyẹn Jerúsálẹ́mù,+ ààlà náà dé orí òkè tó dojú kọ Àfonífojì Hínómù lápá ìwọ̀ oòrùn, èyí tó wà ní ìkángun Àfonífojì* Réfáímù lápá àríwá.

  • Jóṣúà 15:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Ààlà náà lápá ìwọ̀ oòrùn ni Òkun Ńlá*+ àti èbúté rẹ̀. Èyí ni ààlà àwọn àtọmọdọ́mọ Júdà ní ìdílé-ìdílé yí ká.

  • Jeremáyà 7:31
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 31 Wọ́n ti kọ́ àwọn ibi gíga Tófétì, èyí tó wà ní Àfonífojì Ọmọ Hínómù,*+ láti sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná,+ ohun tí mi ò pa láṣẹ, tí kò sì wá sí mi lọ́kàn rí.’*+

  • Jeremáyà 19:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 kí o sì jáde lọ sí Àfonífojì Ọmọ Hínómù,+ tó wà ní ibi àtiwọ Ẹnubodè Èéfọ́ Ìkòkò. Ibẹ̀ sì ni kí o ti kéde àwọn ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún ọ.

  • Mátíù 5:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé gbogbo ẹni tí kò bá yéé bínú+ sí arákùnrin rẹ̀ máa jíhìn fún ilé ẹjọ́; ẹnikẹ́ni tó bá sì sọ̀rọ̀ àbùkù tí kò ṣeé gbọ́ sétí sí arákùnrin rẹ̀ máa jíhìn fún Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ; àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá sọ pé, ‘Ìwọ òpònú aláìníláárí!’ Gẹ̀hẹ́nà* oníná ló máa tọ́ sí i.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́