-
Léfítíkù 20:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Èmi fúnra mi kò ní fi ojú rere wo ọkùnrin yẹn, màá sì pa á, kí n lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀, torí ó ti fún Mólékì lára àwọn ọmọ rẹ̀, ó ti sọ ibi mímọ́+ mi di ẹlẹ́gbin, ó sì ti sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́.
-
-
Jeremáyà 19:5, 6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Wọ́n kọ́ àwọn ibi gíga Báálì láti sun àwọn ọmọ wọn nínú iná bí odindi ẹbọ sísun sí Báálì,+ ohun tí mi ò pa láṣẹ tàbí sọ nípa rẹ̀, tí kò sì wá sí mi lọ́kàn rí.”’*+
6 “‘“Nítorí náà, wò ó! ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “tí a kò ní pe ibí yìí ní Tófétì tàbí Àfonífojì Ọmọ Hínómù mọ́, àmọ́ Àfonífojì Ìpànìyàn la ó máa pè é.+
-