-
Nọ́ńbà 32:20-22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Mósè dá wọn lóhùn pé: “Tí ẹ bá lè ṣe èyí: Kí ẹ gbé ohun ìjà yín níwájú Jèhófà láti jagun+ náà; 21 tí gbogbo yín bá sì gbé ohun ìjà, tí ẹ sọdá Jọ́dánì níwájú Jèhófà nígbà tó ń lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ kúrò níwájú rẹ̀,+ 22 títí a fi máa gba ilẹ̀ náà níwájú Jèhófà,+ nígbà náà, ẹ lè pa dà,+ ẹ ò sì ní jẹ̀bi lọ́dọ̀ Jèhófà àti Ísírẹ́lì. Ilẹ̀ yìí á wá di tiyín níwájú Jèhófà.+
-
-
Diutarónómì 3:18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 “Mo wá pa àṣẹ yìí fún yín pé: ‘Jèhófà Ọlọ́run yín ti fún yín ní ilẹ̀ yìí kó lè di tiyín. Kí gbogbo ọkùnrin yín tó jẹ́ akọni gbé ohun ìjà, kí wọ́n sì sọdá níwájú àwọn arákùnrin yín, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+
-