15 Àmọ́ tó bá dà bíi pé ó burú lójú yín láti máa sin Jèhófà, ẹ fúnra yín yan ẹni tí ẹ fẹ́ máa sìn lónìí,+ bóyá àwọn ọlọ́run tí àwọn baba ńlá yín sìn ní òdìkejì Odò+ tàbí àwọn ọlọ́run àwọn Ámórì tí ẹ̀ ń gbé ní ilẹ̀ wọn.+ Ṣùgbọ́n ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.”