ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 9:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Àmọ́ ìdí tí mo fi dá ẹ̀mí rẹ sí ni pé: kí n lè fi agbára mi hàn ọ́, kí a sì lè ròyìn orúkọ mi ní gbogbo ayé.+

  • Ẹ́kísódù 15:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 Ọwọ́ ọ̀tún rẹ mà lágbára o, Jèhófà;+

      Jèhófà, ọwọ́ ọ̀tún rẹ lè fọ́ ọ̀tá túútúú.

  • Diutarónómì 28:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Gbogbo èèyàn tó wà ní ayé á sì rí i pé orúkọ Jèhófà ni wọ́n fi ń pè ọ́,+ wọ́n á sì máa bẹ̀rù rẹ.+

  • 1 Sámúẹ́lì 17:46
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 46 Lónìí yìí, Jèhófà yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́,+ màá mú ọ balẹ̀, màá sì gé orí rẹ kúrò. Lónìí yìí kan náà, màá fi òkú àwọn tó wà ní ibùdó àwọn Filísínì fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹran inú igbó; gbogbo àwọn èèyàn tó wà láyé yóò sì mọ̀ pé Ọlọ́run kan wà ní Ísírẹ́lì.+

  • 2 Àwọn Ọba 19:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Àmọ́ ní báyìí, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa, jọ̀ọ́ gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, kí gbogbo ìjọba ayé lè mọ̀ pé ìwọ Jèhófà nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run.”+

  • Sáàmù 106:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  8 Àmọ́, ó gbà wọ́n sílẹ̀ nítorí orúkọ rẹ̀,+

      Kí wọ́n lè mọ bí agbára rẹ̀ ṣe pọ̀ tó.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́