-
Ẹ́kísódù 14:17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Ní tèmi, màá jẹ́ kí ọkàn àwọn ará Íjíbítì le, kí wọ́n lè lépa wọn wọnú òkun, kí n sì ṣe ara mi lógo nípasẹ̀ Fáráò àti gbogbo ọmọ ogun rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti àwọn agẹṣin rẹ̀.+
-
-
Jóṣúà 2:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Ó sì sọ fún wọn pé: “Mo mọ̀ pé Jèhófà máa fún yín ní ilẹ̀ yìí+ àti pé ẹ̀rù yín ti ń bà wá.+ Ọkàn gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ yìí sì ti domi nítorí yín,+ 10 torí a ti gbọ́ bí Jèhófà ṣe mú kí omi Òkun Pupa gbẹ níwájú yín nígbà tí ẹ kúrò ní Íjíbítì+ àti ohun tí ẹ ṣe sí àwọn ọba Ámórì méjèèjì, ìyẹn Síhónì+ àti Ógù+ tí ẹ pa run ní òdìkejì* Jọ́dánì.
-
-
1 Kíróníkà 16:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Ẹ máa kéde ògo rẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,
Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ láàárín gbogbo àwọn èèyàn.
-
-
Àìsáyà 63:12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Ẹni tó mú kí apá Rẹ̀ ológo bá ọwọ́ ọ̀tún Mósè lọ,+
Ẹni tó pín omi níyà níwájú wọn,+
Kó lè ṣe orúkọ tó máa wà títí láé fún ara rẹ̀,+
-