13 Ó fún Kélẹ́bù+ ọmọ Jéfúnè, ní ìpín láàárín àwọn àtọmọdọ́mọ Júdà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Jóṣúà, ìpín náà ni Kiriati-ábà, (Ábà ni bàbá Ánákì), ìyẹn Hébúrónì.+ 14 Kélẹ́bù lé àwọn ọmọ Ánákì+ mẹ́ta kúrò níbẹ̀, ìyẹn: Ṣéṣáì, Áhímánì àti Tálímáì,+ àwọn àtọmọdọ́mọ Ánákì.