10 Torí náà, àwọn Filísínì jà, wọ́n ṣẹ́gun Ísírẹ́lì,+ kálukú wọn sì sá lọ sí ilé rẹ̀. Ìpakúpa náà pọ̀; ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ (30,000) àwọn ọmọ ogun tó ń fẹsẹ̀ rìn ló kú lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 11 Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n gba Àpótí Ọlọ́run, àwọn ọmọ Élì méjèèjì, Hófínì àti Fíníhásì sì kú.+