12 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá sọ fún Mósè pé: “A máa kú báyìí, ó dájú pé a máa ṣègbé, gbogbo wa la máa ṣègbé! 13 Kódà, ẹnikẹ́ni tó bá sún mọ́ àgọ́ ìjọsìn Jèhófà máa kú!+ Ṣé bí gbogbo wa ṣe máa kú nìyẹn?”+
8 Àmọ́ inú bí Dáfídì* nítorí pé ìbínú Jèhófà ru sí Úsà; wọ́n sì wá ń pe ibẹ̀ ní Peresi-úsà* títí di òní yìí. 9 Torí náà, ẹ̀rù Jèhófà+ ba Dáfídì ní ọjọ́ yẹn, ó sì sọ pé: “Kí ló dé tí a ó fi gbé Àpótí Jèhófà wá sọ́dọ̀ mi?”+