7 Ààlà náà tún dé Débírì ní Àfonífojì* Ákórì,+ ó sì yí gba apá àríwá lọ sí Gílígálì,+ tó wà níwájú ibi tí wọ́n ń gbà gòkè ní Ádúmímù, ní gúúsù àfonífojì, ààlà náà dé ibi omi Ẹ́ń-ṣímẹ́ṣì,+ ó sì parí sí Ẹ́ń-rógélì.+
15 Torí náà, gbogbo àwọn èèyàn náà lọ sí Gílígálì, wọ́n sì fi Sọ́ọ̀lù jẹ ọba níwájú Jèhófà ní Gílígálì. Wọ́n rú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ níbẹ̀ níwájú Jèhófà,+ Sọ́ọ̀lù àti gbogbo èèyàn Ísírẹ́lì sì ṣe ayẹyẹ pẹ̀lú ìdùnnú ńlá.+