-
1 Kíróníkà 12:39, 40Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
39 Wọ́n fi ọjọ́ mẹ́ta wà níbẹ̀ pẹ̀lú Dáfídì, wọ́n ń jẹ wọ́n sì ń mu, nítorí àwọn arákùnrin wọn ti pèsè nǹkan sílẹ̀ dè wọ́n. 40 Bákan náà, àwọn tó wà nítòsí wọn, títí kan àwọn tó wà ní ilẹ̀ Ísákà, Sébúlúnì àti Náfútálì fi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ràkúnmí, ìbaaka àti màlúù gbé oúnjẹ wá, ìyẹn àwọn ohun tí wọ́n fi ìyẹ̀fun ṣe, ìṣù ọ̀pọ̀tọ́ àti ìṣù àjàrà gbígbẹ, wáìnì, òróró àti màlúù pẹ̀lú àgùntàn tó pọ̀ gan-an, torí pé ìdùnnú ṣubú layọ̀ ní Ísírẹ́lì.
-