ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 8:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 rántí pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ ló fún ọ lágbára láti di ọlọ́rọ̀,+ kó lè mú májẹ̀mú rẹ̀ tó bá àwọn baba ńlá rẹ dá ṣẹ, bó ṣe rí lónìí.+

  • Diutarónómì 28:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Jèhófà máa ṣí ọ̀run, ilé ìkẹ́rùsí rẹ̀ tó dáa fún ọ, láti rọ òjò sórí ilẹ̀ rẹ ní àkókò+ rẹ̀, kó sì bù kún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. O máa yá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ní nǹkan, àmọ́ kò ní sóhun tó máa mú kí o yá+ nǹkan.

  • 2 Kíróníkà 1:11, 12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run sọ fún Sólómọ́nì pé: “Nítorí ohun tí ọkàn rẹ fẹ́ yìí àti pé o ò béèrè ọlá, ọrọ̀ àti ògo tàbí ikú* àwọn tó kórìíra rẹ, bẹ́ẹ̀ ni o ò béèrè ẹ̀mí gígùn,* àmọ́ o béèrè ọgbọ́n àti ìmọ̀ kí o lè máa ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn mi tí mo fi ọ́ jọba lé lórí,+ 12 màá fún ọ ní ọgbọ́n àti ìmọ̀; màá tún fún ọ ní ọlá àti ọrọ̀ àti iyì irú èyí tí àwọn ọba tó ṣáájú rẹ kò ní, kò sì ní sí èyí tó máa ní irú rẹ̀ lẹ́yìn rẹ.”+

  • Jóòbù 42:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Jèhófà wá bù kún ìgbẹ̀yìn ayé Jóòbù ju ti ìbẹ̀rẹ̀ lọ,+ Jóòbù wá ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá (14,000) àgùntàn, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ràkúnmí, màlúù méjì-méjì lọ́nà ẹgbẹ̀rún (1,000) àti ẹgbẹ̀rún (1,000) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.+

  • Òwe 10:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Ìbùkún Jèhófà ló ń sọni di ọlọ́rọ̀,+

      Kì í sì í fi ìrora* kún un.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́