-
2 Àwọn Ọba 6:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Nígbà tí ìránṣẹ́* èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ dìde ní àárọ̀ kùtù, tí ó sì jáde, ó rí i tí àwọn ọmọ ogun pẹ̀lú àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yí ìlú náà ká. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ìránṣẹ́ náà sọ fún un pé: “Áà, ọ̀gá mi! Kí la máa ṣe?” 16 Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Má bẹ̀rù!+ Torí pé àwọn tó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tó wà pẹ̀lú wọn.”+
-
-
2 Kíróníkà 14:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Ásà wá ké pe Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀,+ ó ní: “Jèhófà, kò jẹ́ nǹkan kan lójú rẹ bóyá àwọn tí o fẹ́ ràn lọ́wọ́ pọ̀ tàbí wọn ò lágbára. + Ràn wá lọ́wọ́, Jèhófà Ọlọ́run wa, nítorí ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé,*+ a wá ní orúkọ rẹ láti dojú kọ ọ̀pọ̀ èèyàn yìí.+ Jèhófà, ìwọ ni Ọlọ́run wa. Má ṣe jẹ́ kí ẹni kíkú borí rẹ.”+
-