26 Dáfídì béèrè lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin tó dúró nítòsí rẹ̀ pé: “Kí ni wọ́n máa ṣe fún ọkùnrin tó bá mú Filísínì tó wà níbẹ̀ yẹn balẹ̀, tó sì mú ẹ̀gàn kúrò lórí Ísírẹ́lì? Ta tiẹ̀ ni Filísínì aláìdádọ̀dọ́* yìí tí á fi máa pẹ̀gàn ìlà ogun Ọlọ́run alààyè?”+
36 Àti kìnnìún àti bíárì náà ni ìránṣẹ́ rẹ pa, Filísínì aláìdádọ̀dọ́* yìí á sì dà bí ọ̀kan lára wọn, nítorí ó ti pẹ̀gàn àwọn ìlà ogun Ọlọ́run alààyè.”*+
14 Lẹ́yìn náà, Dáfídì rán àwọn òjíṣẹ́ sí Íṣí-bóṣétì,+ ọmọ Sọ́ọ̀lù, pé: “Fún mi ní Míkálì ìyàwó mi, ẹni tí mo fi ọgọ́rùn-ún (100) adọ̀dọ́ àwọn Filísínì+ fẹ́.”