6 Àlùfáà náà bá fún un ní búrẹ́dì mímọ́,+ torí pé kò sí búrẹ́dì míì nílẹ̀ àfi búrẹ́dì àfihàn, tí a mú kúrò níwájú Jèhófà kí a lè fi búrẹ́dì tuntun rọ́pò rẹ̀ ní ọjọ́ tí a mú un kúrò.
9 Àlùfáà náà bá sọ pé: “Idà Gòláyátì+ ará Filísínì tí o pa ní Àfonífojì* Élà+ wà níbí, òun ni wọ́n faṣọ wé lẹ́yìn éfódì+ yẹn. Tí o bá fẹ́ mú un, o lè mú un, torí òun nìkan ló wà níbí.” Dáfídì wá sọ pé: “Kò sí èyí tó dà bíi rẹ̀. Mú un fún mi.”