-
1 Sámúẹ́lì 25:14-16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Ní àkókò yìí, ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Nábálì ròyìn fún Ábígẹ́lì, ìyàwó Nábálì pé: “Wò ó! Dáfídì rán àwọn òjíṣẹ́ láti aginjù kí wọ́n wá wo àlàáfíà ọ̀gá wa, àmọ́ ṣe ló fi ìbínú sọ̀rọ̀ burúkú sí wọn.+ 15 Àwọn ọkùnrin náà ṣe dáadáa sí wa. Wọn ò pa wá lára rí, bẹ́ẹ̀ ni kò sí nǹkan wa kankan tó sọ nù ní gbogbo ìgbà tí a fi wà lọ́dọ̀ wọn ní pápá.+ 16 Wọ́n dà bí ògiri yí wa ká, ní ọ̀sán àti ní òru, ní gbogbo ìgbà tí a fi wà lọ́dọ̀ wọn, tí à ń tọ́jú àwọn àgùntàn.
-