30Nígbà tí Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ dé sí Síkílágì+ lọ́jọ́ kẹta, àwọn ọmọ Ámálékì+ ti wá kó ẹrù àwọn èèyàn ní gúúsù* àti ní Síkílágì, wọ́n ti gbéjà ko Síkílágì, wọ́n sì ti dáná sun ún.
12Àwọn tó wá sọ́dọ̀ Dáfídì ní Síkílágì+ nígbà tí kò lè rìn fàlàlà nítorí Sọ́ọ̀lù+ ọmọ Kíṣì nìyí, wọ́n wà lára àwọn jagunjagun tó lákíkanjú tó tì í lẹ́yìn lójú ogun.+
20 Nígbà tó lọ sí Síkílágì,+ àwọn tó sá wá sọ́dọ̀ rẹ̀ látinú ẹ̀yà Mánásè ni: Ádínáhì, Jósábádì, Jédáélì, Máíkẹ́lì, Jósábádì, Élíhù àti Sílétáì, àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún Mánásè.+