-
Nọ́ńbà 23:19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
Tó bá sọ ohun kan, ṣé kò ní ṣe é?
Tó bá sì sọ̀rọ̀, ǹjẹ́ kò ní mú un ṣẹ?+
-
-
1 Sámúẹ́lì 2:31-34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
31 Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀ tí màá gba agbára rẹ* àti ti ilé baba rẹ, tí ẹnì kankan nínú ilé rẹ kò fi ní dàgbà.+ 32 Bí mo ti ń ṣe rere fún Ísírẹ́lì, alátakò ni wàá máa rí nínú ibùgbé mi,+ kò tún ní sí ẹni tó máa dàgbà nínú ilé rẹ mọ́ láé. 33 Èèyàn rẹ tí mi ò mú kúrò lẹ́nu sísìn níbi pẹpẹ mi yóò mú kí ojú rẹ di bàìbàì, yóò sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá ọ,* idà àwọn èèyàn ló máa pa èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ará ilé rẹ.+ 34 Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọkùnrin rẹ méjèèjì, Hófínì àti Fíníhásì yóò jẹ́ àmì fún ọ: Ọjọ́ kan náà ni àwọn méjèèjì máa kú.+
-