-
Nọ́ńbà 27:21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Á sì máa dúró níwájú àlùfáà Élíásárì, ẹni tí yóò máa bá a ṣe ìwádìí níwájú Jèhófà nípasẹ̀ ohun tí Úrímù+ bá sọ. Àṣẹ rẹ̀ ni wọ́n á máa tẹ̀ lé tí wọ́n bá ń jáde, àṣẹ rẹ̀ ni wọ́n á sì máa tẹ̀ lé tí wọ́n bá ń wọlé, òun àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú gbogbo àpéjọ náà.”
-
-
1 Sámúẹ́lì 23:2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Torí náà, Dáfídì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà pé:+ “Ṣé kí n lọ mú àwọn Filísínì yìí balẹ̀?” Jèhófà sọ fún Dáfídì pé: “Lọ mú àwọn Filísínì náà balẹ̀, kí o sì gba Kéílà sílẹ̀.”
-
-
1 Sámúẹ́lì 23:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Ṣé àwọn olórí* Kéílà máa fi mí lé e lọ́wọ́? Ṣé Sọ́ọ̀lù máa wá lóòótọ́ bí ìránṣẹ́ rẹ ṣe gbọ́? Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, jọ̀wọ́ sọ fún ìránṣẹ́ rẹ.” Ni Jèhófà bá fèsì pé: “Ó máa wá.”
-