8 Dáfídì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà+ pé: “Ṣé kí n lépa àwọn jàǹdùkú* yìí? Ṣé màá lé wọn bá?” Ó sọ fún un pé: “Lépa wọn, torí ó dájú pé wàá lé wọn bá, wàá sì gba àwọn èèyàn rẹ pa dà.”+
19 Dáfídì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà+ pé: “Ṣé kí n lọ gbéjà ko àwọn Filísínì? Ṣé wàá fi wọ́n lé mi lọ́wọ́?” Ni Jèhófà bá sọ fún Dáfídì pé: “Lọ, torí ó dájú pé màá fi àwọn Filísínì lé ọ lọ́wọ́.”+