3 Jèhófà fetí sí ohùn Ísírẹ́lì, ó sì fi àwọn ọmọ Kénáánì lé wọn lọ́wọ́, wọ́n sì pa àwọn àti àwọn ìlú wọn run pátápátá. Wọ́n wá pe orúkọ ibẹ̀ ní Hóómà.*+
17 Àmọ́ Júdà ń tẹ̀ lé Síméónì ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ, wọ́n gbéjà ko àwọn ọmọ Kénáánì tó ń gbé Séfátì, wọ́n sì pa wọ́n run.+ Wọ́n wá pe orúkọ ìlú náà ní Hóómà.*+