-
1 Kíróníkà 10:1-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Nígbà náà, àwọn Filísínì ń bá Ísírẹ́lì jà. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sá kúrò níwájú àwọn Filísínì, ọ̀pọ̀ lára wọn sì kú sórí Òkè Gíbóà.+ 2 Àwọn Filísínì sún mọ́ Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn Filísínì sì pa Jónátánì, Ábínádábù àti Maliki-ṣúà,+ àwọn ọmọ Sọ́ọ̀lù. 3 Ìjà náà le mọ́ Sọ́ọ̀lù, ọwọ́ àwọn tafàtafà+ bà á, wọ́n sì dá ọgbẹ́ sí i lára. 4 Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ fún ẹni tó ń bá a gbé ìhámọ́ra pé: “Fa idà rẹ yọ, kí o sì fi gún mi ní àgúnyọ, kí àwọn aláìdádọ̀dọ́* yìí má bàa wá hùwà ìkà+ sí mi.”* Àmọ́, ẹni tó ń bá a gbé ìhámọ́ra kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ẹ̀rù bà á gan-an. Torí náà, Sọ́ọ̀lù mú idà, ó sì ṣubú lé e.+ 5 Nígbà tí ẹni tó ń bá a gbé ìhámọ́ra rí i pé Sọ́ọ̀lù ti kú, òun náà ṣubú lé idà tirẹ̀, ó sì kú.
-