25 Sọ́ọ̀lù dá Dáfídì lóhùn pé: “Kí Ọlọ́run bù kún ọ, Dáfídì ọmọ mi. Ó dájú pé wàá gbé àwọn ohun ńlá ṣe, wàá sì borí.”+ Ìgbà náà ni Dáfídì bá tiẹ̀ lọ, Sọ́ọ̀lù sì pa dà sí àyè rẹ̀.+
7 Ìgbà náà ni Nátánì sọ fún Dáfídì pé: “Ìwọ ni ọkùnrin náà! Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Èmi ni mo fòróró yàn ọ́ ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì,+ mo sì gbà ọ́ lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù.+