35 Ní òru ọjọ́ yẹn, áńgẹ́lì Jèhófà jáde lọ, ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀rún márùn-ún (185,000) ọkùnrin nínú ibùdó àwọn ará Ásíríà.+ Nígbà tí àwọn èèyàn jí láàárọ̀ kùtù, wọ́n rí òkú nílẹ̀ bẹẹrẹbẹ.+
22 Ọlọ́run mi rán áńgẹ́lì rẹ̀, ó sì dí àwọn kìnnìún náà lẹ́nu,+ wọn ò sì ṣe mí léṣe,+ torí ó rí i pé mi ò mọwọ́ mẹsẹ̀; mi ò sì ṣe ohun burúkú kankan sí ìwọ ọba.”
18 Wọ́n gbá àwọn àpọ́sítélì mú,* wọ́n sì tì wọ́n mọ́ inú ẹ̀wọ̀n ìlú.+19 Àmọ́ ní òru, áńgẹ́lì Jèhófà* ṣí àwọn ilẹ̀kùn ẹ̀wọ̀n náà,+ ó mú wọn jáde, ó sì sọ pé:
11 Bí Pétérù ṣe wá mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Ní báyìí, mo ti mọ̀ dájú pé Jèhófà* ló rán áńgẹ́lì rẹ̀ láti gbà mí lọ́wọ́ Hẹ́rọ́dù àti lọ́wọ́ gbogbo ohun tí àwọn Júù ń retí pé kó ṣẹlẹ̀.”+