-
2 Sámúẹ́lì 1:13-15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Dáfídì béèrè lọ́wọ́ ọ̀dọ́kùnrin tó wá ròyìn fún un pé: “Ibo lo ti wá?” Ó sọ pé: “Ọmọ Ámálékì ni bàbá mi, àjèjì ni nílẹ̀ Ísírẹ́lì.” 14 Ìgbà náà ni Dáfídì sọ fún un pé: “Kí ló dé tí ẹ̀rù ò fi bà ọ́ láti gbé ọwọ́ rẹ sókè láti pa ẹni àmì òróró Jèhófà?”+ 15 Dáfídì bá pe ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀, ó sì sọ pé: “Bọ́ síwájú, kí o sì ṣá a balẹ̀.” Torí náà, ó ṣá a balẹ̀, ó sì kú.+
-