-
Ẹ́kísódù 25:22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Màá pàdé rẹ níbẹ̀, màá sì bá ọ sọ̀rọ̀ látorí ìbòrí náà.+ Láti àárín àwọn kérúbù méjì tó wà lórí àpótí Ẹ̀rí náà ni màá ti jẹ́ kí o mọ gbogbo ohun tí màá pa láṣẹ fún ọ pé kí o sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
-
-
1 Kíróníkà 13:6-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Dáfídì àti gbogbo Ísírẹ́lì lọ sí Báálà,+ sí Kiriati-jéárímù ti Júdà, kí wọ́n lè gbé Àpótí Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ wá láti ibẹ̀, ẹni tó ń jókòó lórí* àwọn kérúbù,+ ibi tí a ti ń ké pe orúkọ rẹ̀. 7 Àmọ́, wọ́n gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ sórí kẹ̀kẹ́ tuntun,+ wọ́n gbé e wá láti ilé Ábínádábù. Úsà àti Áhíò sì ń darí kẹ̀kẹ́ náà.+ 8 Dáfídì àti gbogbo Ísírẹ́lì ń ṣe ayẹyẹ níwájú Ọlọ́run tòótọ́ tọkàntara pẹ̀lú orin, háàpù, àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín, ìlù tanboríìnì+ àti síńbálì*+ pẹ̀lú kàkàkí.+ 9 Àmọ́ nígbà tí wọ́n dé ibi ìpakà Kídónì, Úsà na ọwọ́ rẹ̀, ó sì gbá Àpótí náà mú, torí màlúù náà mú kí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dojú dé. 10 Ni ìbínú Jèhófà bá ru sí Úsà, Ó pa á nítorí pé ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì gbá Àpótí+ náà mú, torí náà, ó kú síbẹ̀ níwájú Ọlọ́run.+ 11 Àmọ́ inú bí Dáfídì* nítorí pé ìbínú Jèhófà ru sí Úsà; wọ́n sì wá ń pe ibẹ̀ ní Peresi-úsà* títí di òní yìí.
-