-
1 Àwọn Ọba 5:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Torí náà, mo fẹ́ kọ́ ilé kan fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run mi, bí Jèhófà ti ṣèlérí fún Dáfídì bàbá mi pé: ‘Ọmọ rẹ tí màá fi sórí ìtẹ́ rẹ láti rọ́pò rẹ ni ó máa kọ́ ilé fún orúkọ mi.’+
-
-
Sekaráyà 6:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Kí o sì sọ fún un pé,
“‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Ọkùnrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Èéhù+ rèé. Yóò hù jáde láti àyè rẹ̀, yóò sì kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà.+ 13 Òun ni yóò kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà, òun ni iyì máa tọ́ sí. Yóò jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, yóò sì ṣàkóso, yóò sì tún jẹ́ àlùfáà lórí ìtẹ́ rẹ̀,+ ọ̀kan kò sì ní pa èkejì lára.*
-