-
1 Kíróníkà 22:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Wò ó! Wàá bí ọmọkùnrin kan+ tó máa jẹ́ ẹni àlàáfíà,* màá sì fún un ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ tó yí i ká,+ Sólómọ́nì*+ ni orúkọ tí a máa pè é, màá sì fi àlàáfíà àti ìparọ́rọ́ jíǹkí Ísírẹ́lì ní ìgbà ayé rẹ̀.+ 10 Òun ló máa kọ́ ilé fún orúkọ mi.+ Á di ọmọ mi, màá sì di bàbá rẹ̀.+ Màá fìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì títí láé.’+
-
-
2 Kíróníkà 2:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Ní báyìí, mo fẹ́ kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run mi, láti yà á sí mímọ́ fún un, láti máa sun tùràrí onílọ́fínńdà+ níwájú rẹ̀ àti láti máa kó búrẹ́dì onípele* síbẹ̀ ní gbogbo ìgbà+ àti àwọn ẹbọ sísun ní àárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́,+ ní àwọn Sábáàtì,+ ní àwọn òṣùpá tuntun+ àti ní àwọn àsìkò àjọyọ̀+ Jèhófà Ọlọ́run wa. Ohun tí Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ máa ṣe nìyẹn títí láé.
-