-
1 Kíróníkà 18:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Dáfídì ṣẹ́gun Hadadésà+ ọba Sóbà+ nítòsí Hámátì,+ bí ó ṣe ń lọ fìdí àkóso rẹ̀ múlẹ̀ ní odò Yúfírétì.+ 4 Dáfídì gba ẹgbẹ̀rún (1,000) kẹ̀kẹ́ ẹṣin, ẹgbẹ̀rún méje (7,000) agẹṣin àti ọ̀kẹ́ kan (20,000) ọmọ ogun tó ń fẹsẹ̀ rìn lọ́wọ́ rẹ̀.+ Dáfídì sì já iṣan ẹsẹ̀* gbogbo àwọn ẹṣin tó ń fa kẹ̀kẹ́ ogun, àmọ́ ó dá ọgọ́rùn-ún (100) lára àwọn ẹṣin náà sí.+
-